Job 6

Ìdáhùn Jobu

1Jobu sì dáhùn ó si wí pé:

2“Háà! À bá lè wọ́n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n,
kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!
3Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìbá wúwo jú iyanrìn Òkun lọ:
nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé
4Nítorí pé ọfà Olódùmarè wọ̀ mi nínú,
oró èyí tí ọkàn mi mú;
ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.
5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko,
tàbí ọ̀dá màlúù a máa dún lórí ìjẹ rẹ̀?
6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀,
tàbí adùn ha wà nínú funfun ẹyin?
7Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò,
òun ni ó dàbí oúnjẹ tí ó mú mi ṣàárẹ̀.

8“Háà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà;
àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.
9Àní Ọlọ́run ìbá jẹ́ pa mí run,
tí òun ìbá jẹ́ ṣíwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.
10Nígbà náà ní èmi ìbá ní ìtùnú síbẹ̀,
àní, èmi ìbá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí:
nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí?
Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?
12Agbára mi ha ṣe agbára òkúta bí?
Ẹran-ara mi í ṣe idẹ?
13Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi:
ọgbọ́n kò ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá,
kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódùmarè sílẹ̀?
15Àwọn ará mi dàbí odò tí kò ṣe gbẹ́kẹ̀lé
bí ìṣàn omi odò, wọ́n sàn kọjá lọ.
16Tí ó dúdú nítorí omi dídì,
àti níbi tí yìnyín dídì gbé di yíyọ́.
17Nígbàkúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ sàn lọ,
nígbà tí oòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.
18Àwọn oníṣòwò yà kúrò ní ọ̀nà wọn,
wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.
19Ẹgbẹ́ oníṣòwò Tema ń wá omi,
àwọn oníṣòwò Ṣeba ń dúró dè wọ́n ní ìrètí.
20Wọ́n káàárẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé e;
wọ́n dé bẹ̀, wọ́n sì dààmú.
21Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ̀yin dàbí wọn;
ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.
22Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá,
tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?
23Tàbí, ẹ gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni,
tàbí, ẹ rà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì’?

24“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́
kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti ṣìnà.
25Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó
ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbáwí yín jásí?
26Ẹ̀yin ṣè bí ẹ tún ọ̀rọ̀ mi ṣe
àti ohùn ẹnu tí ó dàbí afẹ́fẹ́ ṣe àárẹ̀.
27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba,
ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín.
Ẹ má wò mi! Nítorí pé ó hàn gbangba pé:
Ní ojú yín ni èmi kì yóò ṣèké.
29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀;
àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.
30Àìṣedéédéé ha wà ní ahọ́n mi?
Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?
Copyright information for YorBMYO